Ọ̀GÁ MÉJÌ.

Àwọn agbára méjì ló wà ní ayé yí, tí wọn fẹ́ láti ṣẹ́gun àti láti jọba lórí àwọn ọmọ ènìyàn. Ọkàn nínú wọn jẹ́ Ìjọba ti Ọlọ́run pẹ̀lú Kristi Olúwa tó ń darí rẹ. Gbogbo wa lo wá lábẹ́ ìtẹríba fún ọkàn nínú àwọn agbára ńlá yìí. Olúkúlùkù wa lo ni olórí tí ṣe ọkàn nínú àwọn Ọ̀gà alágbára wọ̀nyí. Jésù wípé: “kò sí ẹni tí ó lè sin Olúwa méjì” (Matt. 6:24), ju bẹ́ẹ̀ lọ, “Ẹnití kò bá wà pẹ̀lú mi, ó ńṣe òdì sí mi, ẹni tí kò bá sí bá mi kò pọ̀, ó nfọ́nka.” (Matt. 12:30). Báyìí ni gbogbo wa, là jẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ lábẹ́ ọ̀kan tàbí èkejì nínú wọn. Àwọn méjèèjì ló ní ìtara sì wa láti jẹ olusin wọn. Àwọn ẹ̀bùn àti orisirisi ìlérí tí ọ̀ga ìjọba ayé yìí ṣe fún sìnsin wá dabi pé wọ́n wuni, wọ́n sì pọ̀; díẹ̀ nínú wọn ni ìgbésí ayé tó l'ádùn láì ni ìṣòro pẹ̀lú fàájì púpọ̀, lílọ sì íjó, wíwòran atafo-ojú (cinema), tẹ́tẹ́, títa ayò ìwé pẹlẹbẹ (card), lílọ síbi ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ àti sí ibi tí wọ́n ti nse àsè. Èṣù gbìyànjú láti fi gbogbo nkàn tí ó bá ń fẹ́ láti ni fún ọ, ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, kò ṣe ìlérí fún ọ ní ti ẹ̀yìn ayé yìí, kò sọ fún ọ nípa ọjọ́ ẹ̀san ńlá èyí tí ó mbọ̀ wá tàbí tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ tí wọ́n dúró de èrè wọn ti ìṣe iná-àjóòkú tí a ti pèsè sílè fún èṣù àti àwọn áńgẹ́lì rẹ̀. (Matt. 25:40-46). Kò tilẹ̀ rán ọ létí pé òun ni ẹni tí ó wà nìdí gbogbo ẹ̀sẹ̀, ìtìjú, ìmúlẹ̀-mófo, ìbànúnjẹ́ àti ikú pãpã tìkára rẹ̀ tó wà nínú ayé yìí. Ăh, irú ọ̀gá báyìí!

Fún Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọ̀rọ̀ lórí Ọ̀GÁ MÉJÌ.

Ọ̀ga kejì ni Olúwa Ọlọ́run. Lakọ̀ọ́kọ́, kíyèsí irú ipò tí ọ̀gá yii wa – “Gbogbo agbára li ọ̀run àti ní ayé li a fi fún mi.”(Matt. 28:18). Ó lè máa yà ọ lẹ́nu pé kí ni ọ̀gá eléyìí ni láti fúnni fún iṣẹ́ tí à bá ṣe fún un. Fún ìtìlẹyìn, un ó sọ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọ̀gá yíì wí fúnra Rẹ̀: “Nitori Ọlọrun fẹ araiye tobẹ̃ gẹ, ti o fi Ọmọ bíbi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ́ MÁ BÀA ṢÈGBÉ , ṣugbọn ki Ó LEÈ NÍ ÌYÈ ÀÌNÍPÈKUN ̣.”(Jòhánù 3:16). A óò yè títí láé ni ìlérí ńlá àkọ́kọ́ yí, ẹ jẹ̀ki a tún Ọ̀gá yìí. “Ṣugbọn nisisiyi li aiye yi on o si gbà ọgọrọrun , ile, ati arakunrin, ati arabinrin, ati iya, ati ọmọ, ati ilẹ, pẹlu inunibini, ati li aiye ti mbọ̀ ìye ainipẹkun;”(Maku 10:30). Nípa èyí á rí pé Krístì Olúwa ní nnءkan pàtàkì tí ṣe ìbùkún tí ń fẹ́ láti fúnni àwọn tí ó sìn ín lótitọ́, nínú ayé yìí àti ayé tí mbọ̀, “… Ohun ti oju kò ri, ati ti etí kò gbọ, ti kò si wọ ọkàn enia lọ, ohun wọnni tiỌlọrun ti pèse silẹ fun awọn ti o fẹ Ẹ.”(I Kọ́r. 2:9). Báwo ni ògo ọjọ́ ẹ̀san Olúwa yíò ti rí. Báwo ni ó ṣe yàtọ̀ sí ti Èṣù.

Láti rí àwọn ìbùkún títóbi yí gbà lọ́wọ́ Ọ̀gá alágbára yi, o gbọ́dọ̀ jọ̀wọ́ ara rẹ pátápátá fún Un, ati láti jẹ́ olùgbọ́ran sí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ, yíyà kúrò fún ẹ̀sẹ̀, ìjẹ́wọ́ àti ìkọ̀ sílẹ̀ àwọn ẹ̀sẹ̀ tí ìgbésí ayé rẹ ti o ti lò kọjá nínú ẹ̀sẹ̀, lẹ́hìn náà, Ó béèrè lọ́wọ́ rẹ pé kí ó ṣẹ́ ara rẹ, nípa oore ọ̀fẹ́ Rẹ, kí ó má se lọ́wọ́ nínú àwọn iṣẹ́ èṣù gẹ́gẹ́ bí igbàdùn ayé, ásè, ìfẹ́kúfẹ́ ara, àwàdà àti ìṣẹ̀fẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, lọ́nà kejì kí o sì máa gbé ìgbésí ayé tó mọ́, ìwọ̀ntunwọ̀nsì, mímọ́-tótó, olótitọ́, pẹ̀lú ìgbésí ayé ìwà-bí-Ọlọ́run láti máa bẹ àwọn aláìsàn wò, àwọn tálákà, àti láti fẹ̀ràn gbogbo ènìyàn àti láti máa gbàdúrà fún gbogbo wọn.

Olúwa àti gbogbo àwọn tó sìn I ní iṣẹ́ pàtàkì tí ó tóbi pẹ̀lú ìbùkún láti ṣe, láti yí gbogbo ènìyàn lọ́kàn padà, láti máa sìn Olúwa, láti jẹ alábàápín nínú àwọn ìlérí iyebíye Rẹ tí YÓÒ mú ṣẹ fún gbogbo àwọn tí ó jẹ olótitọ́ sì I gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gá wọn.

Èmi tìkára mi tí ni ìrírí nípa ṣinṣin àwọn ọ̀gà méjèèjì yí: Nígbà tí mo sin tì ṣáájú (Èyí búburú ni) mo rò pé mo nlo àkókò tí ó dára nípa gbígbé ayé fàájì, mi ò bìkítà nípa èrè ọjọ́ iwájú. Ṣùgbọ́n l'àárọ̀ ọjọ́ kan, nígbà tí mo sùn lórí ibùsùn mi, Ọ̀gá rere náà tọ mí wá li ọ̀nà tí ó ṣe pàtàkì, tí ó sì fi nkàn tí ó bá ní lẹ̀ru yí hàn fún mi: Nípa gbígbójú wo apá kan ibìsùn mi, mo rí ohun kan tí ó dàbí ihò iná, àwọn ẹ̀ẹ́fín àti ọ̀wọ́ iná rẹ ga lọ sókè. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, mo mọ̀ lára pé wọ́n tì mí sí inú ihò iná yí, tó dàbí pé kò ní ìsàlẹ̀. Níbí yí ni a ti fi ìjìyà tí ó bá mí lẹ̀ru rèkọjá hàn mí nípa ṣísin ẹni burúkú ni, tí yóò jẹ́ ipò mi bí nkó bá yí padà kúrò nínú ìgbésí ayé ẹ̀sẹ̀

mi. Mo ṣe ìlérí fún Ọ̀gá rere nígbànáà pé, n ó fi gbogbo ọjọ́ ayé mi sìn ín bí wọ́n bá lè gbà mí kúrò nínú ìparun búburú yìí, mo jẹ́ri sì pe Ọ̀gá yìí dára jù lọ láti sìn, mo sì ní ayọ̀ ati ìtẹ́lọ́rùn tí Ọ̀gá mi tẹ́lẹ̀ kò lè fún mi, mo tún mọ̀ pẹ̀lú nípa ti èrè ńlá ti ìyè àìnípẹ̀kun tí a óò fi fún àwọn olóòótọ́.

Olùkàwé mi ọ̀wọ́n, mo na ọwọ́ ìpè yí sí ọ, láti jọ̀wọ́ ara rẹ pátápátá fún Ìfẹ́ àti Òtítọ́ tí ìsìn Ọ̀gá yìí. Jésù wípé, “Emi ni oluṣọ-agutan rere,… - … mo si fi ẹmí mi lelẹ nitori awọn agutan.”,(àwa) (Jòhánù 10:14-15). “Ṣugbọn iye awọn ti o gbà a, awọn li o fi agbara fun lati di ọmọ Ọlọrun, ani awọn na ti o gbà orukọ rẹ̀ gbọ́:”(Jòhánù 1:12). Áà, ànءfààní wo nìyí, kí ìṣe kìkì Olùsìn nìkan, ṣùgbọ́n ẹ ó di ọmọ pẹ̀lú bí ẹ bá jẹ kí Ó wọ inú ọkàn yín. Yí kúrò lọ́dọ̀ Èṣù, tó ti pèrò láti fi èdìdì di ìparun rẹ láéláé, wá sọ́dọ̀ Jésù nísinsìnyí, kí ó sì jẹ kí ó jẹ Olùgbàlà ati Ọ̀gá rẹ kì ó sì rí ayọ̀ gidi gbà àti Ìyè àìnípẹ̀kun.

Ẹ pé Wàá

Béèrè fún àwọn ìwé ìléwọ́